Àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá
Ètò àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá fún ìjọ àti fún àwùjọ iṣẹ́ ìsìn kọ̀ọ̀kan.
Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni fídíò náà wà. Àwọn ìgbésẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣàlàyé ohun kan náà ní èdè rẹ.
Ìgbésẹ̀ lẹ́yìn ìgbésẹ̀
Ètò náà
Ètò àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá nìyí: fún gbogbo ìjọ àti fún àwùjọ iṣẹ́ ìsìn kọ̀ọ̀kan.
Fi ìpàdé kún un
Tẹ “Fi ìpàdé kún un” kí o sì yan ọjọ́ àti àkókò, ẹni tó wà fún àti ibi tí a ti máa pàdé. Ìpàdé kan lè máa wáyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí kó wáyé lẹ́ẹ̀kan péré.
Ẹni tó máa darí
Fún àwọn ìpàdé ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń yan olùdarí fún déètì kọ̀ọ̀kan nínú àtòjọ àwọn ìpàdé tó ń bọ̀.
Àlàyé nípa ìpàdé
Ṣí ìpàdé kan láti rí olùdarí, ibi tí a ti máa pàdé pẹ̀lú àwọn ìtọ́ni lórí àwòrán ilẹ̀ àti àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù fún ọjọ́ náà.
Àwọn ìpàdé àwùjọ
Àwọn alábòójútó àwùjọ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn ló ń ṣètò àwọn ìpàdé àwùjọ wọn níbí.